YEAR 2025 (Live)-文本歌词

YEAR 2025 (Live)-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

Mo kí gbogbo wa kú ọdún

Ẹ̀mí wa á ṣe púpọ̀ ọdún láyé

Lówó lọ́mọ àìkú baálẹ̀ ọrọ̀ pẹ̀lú àlàáfíà nínú ara

Ojú ẹni ma là á rí tó

(Ojú ẹni ma là á rí ìyọnu)

Ọmọ mi aláyọ̀ká

Ọmọ mẹ́ta là á bí

Ọmọ tá a fẹnu bí

Èyí tá a fojú bí

Àti èyí tá a fọkàn bí

Èyí tó yàtọ̀ nínú mẹ́tẹ́ẹ̀ta o

Èyí tá a bí lójú ara

Bernard b’éèyàn bá ń tọrọ ọmọ lọ́wọ́ Ọlọ́hun Ọba o

Kó larí ẹ̀, kó yàn-án

Ṣé ẹ rí ọmọ tá a fojú ara bí?

Ólè jẹ́ ọmọ aláyọ̀

Tó ti balẹ̀ ọkàn fáwọn tó bí mi lọ́mọ o

Wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi jọjọ

Bó bá ń hùwà dáadáa ní ìdàkejì

Tí inú òbí ò bá dùn

Wọn ò ní’hun méjì tí wọ́n máa ṣe

Ju kí wọ́n ké pe Ọlọ́hun Ọba lọ

Kó bá wọn yi padà sí rú ọmọ tí wọ́n ń fẹ́

Ìgbà tí wọn ò kúkú ní pa á

Orí ẹni ló ń gbé aláwo’re ko ni o

Tó bá ní opportunity gẹ́gẹ́ bí òbí

Tó bọ́ sí àárín àdúgbò, ibẹ̀ ló ti máa r’ọ́mọ kan tó ń ṣe dáadáa

Á wá mú ìfẹ́, á ko sára ọmọ ọ̀hún

Nírètí wí pé òun fojú ri o, òun fọkàn tọrọ lọ́wọ́ Ọlọ́hun Ọba o

Ọmọ tí mò ń wò yìí, kó jẹ́ ọmọ dáadáa

Ṣé ọmọ tèmi náà bẹ́ẹ̀

Ọ̀rọ̀ ń bọ̀ níbẹ̀ lọ́jọ́ iwájú

Aminata, ikú òní pa ẹ́ fún mi Èjìrẹ́ o

Gbogbo ọmọ tó bá ti ń ṣe dáadáa o

Tí a bí lólóríire ọmọ

Tó yẹ kó gbọ̀tún, tó dẹ̀ gbọ̀tún náà

T’órí ẹ̀ gbé aláwo’re pàdé ẹ̀

Ó ń ṣe dáadáa

Á wá máa ṣe àdúà fun

Ọlọ́hun má ṣe bà ẹ́ jẹ́

Ṣá má a ṣe àmín

Àdufẹ́ adé, ara àwọn ọmọ tí mo fínú, f’ojú, fọkàn bí, fẹnu bí

Tó sì ń ṣe dáadáa, Àdufẹ́

Congratulations Àdufẹ́ Adé

Ayé ń mọ̀ ẹ́, Àwọn kọ́ l’Ọlọ́hun Ọba tó dá ẹ o

Mo tí ń sọ fún ẹ

Muhammed Kazeem ọmọ Atóyegbé

Gbogbo yín n mo rí l’ọ́dún yìí

Bá a ṣe péjú sí bí

Mo bẹ̀ ẹ́ Ọlọ́hun Ọba o

Ìmáaka ń í bí’lẹ̀ bá mọ́ kó má jẹ̀ẹ́ ní ti yara wa ní tẹ̀mí tẹ̀mí

Ká délé láyọ̀, àdélébáre ó, àrìnnà ko’re

Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń bẹ ní Nàìjíríà

Iṣẹ́ ẹ yín á rójú, ọ̀na yín á ráyè

Èyítẹ́ ẹ ti ṣe kò ní bàjẹ́

Tuntun tí ẹ̀ ń retí lọ́wọ́ Elédùmarè á wálé

Á bọ́ sí wa lọ́wọ́ jọjọ

Ẹ̀yin tẹ́ ẹ wá láti ìlú òyìnbó

Ayọ̀ lẹ wá’bí

Ayọ̀ lẹ ó padà sí’lé, ẹ̀yin èrò láti ìlú London

Gbogbo Europe lápapọ̀ tẹ́ ẹ wá láti America

Tẹ́ ẹ wá láti Canada, tó fi dé Australia

Ẹ káàbọ̀ sí ìlú Nàìjíríà

Àgbà inú u wa á dò'gbó

Ọmọdé inú u wa á dàgbà

Aboyún ilé e wa á bí wẹ́rẹ́

Àgàn tí ò bí á tọwọ́ àlà b’osùn

Ọdún yìí tá a péjú síbí, Hunter

O ṣe eléyìí, ó ń làmìlaka lójoojúmọ́

Ihun orí bá fi rán èèyàn á máa ṣe é

Àjàgbayì ni tẹdun , Àjàgbayì ni tàrá

Olórí ọ̀dọ́ Orchado máa wolẹ̀ kú ọdún

Hunter Àjàgbayì ni tẹdun , Àjàgbayì ni tàrá

Èyí tó o tún máa ṣe ọlọ́dún tó ń bọ̀ á tún pelemọ ju eléyìí lọ o lọ́lá Ọlọ́hun Ọba

Ọlọ́hun á wá f’ààyè gbà ẹ́, àyè owó

Á gbà ẹ́ láyè, kó ba ń tẹ́ pẹ̀pẹ́ ètò

O ò ní relẹ̀ láyé láyé

Modúpẹ́ t’America o kú àdúrótì Modúpẹ́ ti Canada

O mà kú àdúrótì Hunter

K1 De Ultimate mé le gbàgbé ẹ láéláé

Doro Bucci, Doro

Ilé á tura o, ilé á tura

Mo kí olórí National Union ní Lagos State

Adékúnlé, Walimustapha Dodo

Gbogbo yín ẹ kú ọdún, ìwọ àti àwọn Team ẹ o

Gbogbo yín ni mo kí

Àmọ́dún lójú pé kẹ́sẹ̀ ó pèlé

Mo wá gba ara tì ẹ mo fi kí National President

Àyìndé Musiliu Ayédáadé

Mo kí gbogbo ṣàkọ̀tún, ṣàkòsì

Gbogbo ẹ̀yin captain captain, Ẹ̀yin general general

Ẹ̀yin air vice marshal, Ẹ̀yin Chief Marshal tó ń bẹ níkàlẹ̀

Gbogbo ẹ̀yin ọ̀gá lórí ogun o, ọ̀gá lójú ogun

Mo kí gbogbo Captain tó ń bẹ níkàlẹ̀ mo kí i yín

Ohùn kan la ma fi bára wa sọ̀rọ̀, Adékúnlé

Ìlú òní tóbi o, kápá òrò má ṣe ka

Gbogbo yín pátá pátá ẹ kú àdúrótì Hunter ní n dúpẹ́

Èmi tìkálára ó, mo mọ̀ ọ́ lóore

Látètèkọ́ṣe, lọ̀rọ̀ rẹ ti wà bàbá

Kéèyàn tó bọ́ síwájú

Kó tó máa léṣẹ́ nínú ọdún tuntun o

Tó bá jẹ ẹni tó mọ Ọlọ́hun o

Gbàdúrà, ní ìṣẹ́jú kan o

Kó o fi lé iwájú, Auzubillah minashaitan nirajeem

Mo wá ìṣọ́rí lọ́wọ́ Ọlọ́hun Ọba o

Arínúróde olùmọ̀ràn ọkàn

Mo dẹ̀ tún ń bẹ̀bẹ̀, k’Ọ́lọ́hun Ọba yàwá yèṣù

Ihun máa f’èdè àìyédè níbí Ọlọ́hun Ọba o

Bá wa kájú ẹ̀, kí ìfẹ́ Ọlọ́hun Ọba kó gbilẹ̀

Bá a bá jáde níbí, tá a bá ń relé ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wa ọdún yìí

Owó tí wọ́n ṣe ìlérí pé ó máa dé, Jẹ́ ó máa bẹ̀rẹ̀ sí ní máa sọ̀kalẹ̀ o

K’émi ó máa rí tèmi ṣe, k’íwọ náà kó rí tì ẹ ṣe

Àpèmọ́ra là ń pé tèmidire, Murphy ọwọ́ ẹ ò ní táwọ́ ná

Kò ní kan Ìsàlẹ̀ àpò, Aláṣẹ Wozam, Wozam International

Wozam Arena, Wozam Properties, o ò ní kú ko tó kú

O ò ní dùbúlẹ̀ àìsàn, ẹniẹlẹ́ni ò ní gba ìṣe ẹ ṣe

Àárín èmi àti ẹ kẹ̀dẹ̀ré, kò ní ìbàjẹ́ Ọlọ́hun Ọba

Polanco, mo kí ẹ gbèje gbẹ̀jọ

Ọmọ Imam àgbà ní imalé o

Ajífikálàmù dá wọn lẹ́kun arí ṣe kándú kándú nílùú àgọ́ ìwòyè

Ẹlẹlẹ Mairo, owó ọkọ Mosúnmọ́lá, èèyàn ti Bello

Èèyàn Jẹ́jẹ́ Motors, iṣẹ́ ẹ ti lérè báyìí kò ní dìbàjẹ̀

Mo gbàá ní àdúrà nínú àwọn tó ń ta motor gidi o

Ètí inú, mo wà lórí àdúà

Polanco, wàá ta motor, bí o ṣé ń tàá lọ́wọ́ lọ́wọ́ yìí

Ọlọ́hun á f’ààyè gbà ẹ́

Wàá dédé jí níjọ̀ kan o, wàá bọ́ sórí aeroplane

Bó ṣe máa jẹ́ nìyen, Àdúrà ẹ ti gbà o ò ní ṣubú

Ẹni ma dà ẹ́ lẹ́rù nù, ìyẹn ò ní dé ọ̀dọ̀ tì ẹ

Gbogbo yín pátápátá ọmọ ṣiṣẹ́ ṣiṣẹ́ tí ẹ̀ ń fọwọ́ ṣíṣe

Ẹrù yín ò ní dànù, ẹ ẹ̀ dẹ̀ ní lójú ẹkún

Àdúrà wa á gbà gbogbo yín ni mo kí

Immortal

Èèyàn tèmi Ọmọ́gbọ́láhàn mi ṣọ́ ‘ọbẹ̀

B’ọ́n bá gbẹ́ kòtò sílẹ̀, tí wọ́n bá gbẹ́ní le lórí, immortal

Inákíná tí wọ́n dálẹ̀ di ẹyẹ gúnnugún, ẹyẹ míì ni wọ́n fi ń sun jẹ

Egbèje irawo kò lè mọ́lẹ̀ tó’òòpá

Mo tún fẹ́ ṣ’àdúrà, D Owner

Ayé ò ní nà ẹ́