Wàásí Àyìndé
Ọba mògún
Ishola mi Raufu, àfi ìgbà tó o wá bí
Ọmọ Amusa ní Cotonou
(igbo dialect)
Ishola mi Raufu
Ishola, ọmọ Amusa ní Cotonou
Ishola ọkọ Suraja
Èrò tó ń lọ sí Benin mi, Benin Republic mi
To bá délé bá mi kí Shakira
Àti Sofiatu ní Cotonou
Kí o bá mi kí Bumihu ní Cotonou ọmọ Bílékọlé
Tí o bá dé Cotonou, aristo ní Cotonou
Pẹ̀lú Raliatu ní Cotonou Àbẹ̀bí o, bumihu ní Cotonou
Kí o bá mi kí mọ́gàjí ọ̀dọ́, Tiam
Gbogbo wọn ní Cotonou ọmọ Kula Muinu ní Cotonou
Aláúsá, lawali ní Cotonou
Àyìndé ọ̀rẹ́ wa, gbogbo ẹgbẹ́ Fàdákà ní Cotonou
Àtemi Olúayé òní Fújì Arábámbí
Ọmọ ẹgbẹ́ Fàdákà Àyìndé adé, fàdákà ní Cotonou
Ọmọ Amusa ní Cotonou l’Àyìndé o
Èmi l’ẹ̀gbọ́n Loreture Amusa Ìṣọ̀lá
Èmi náà ọmọ t’àkútù ní Cotonou ọmọ loretu ní Cotonou
Ìṣọ̀lá adé ọmọ Amusa mo kí ẹ
One more time
Ìṣọ̀lá Raufu mi ọmọ ìyálájé
Ọ̀jẹ̀ ló l’òkété bàbá wọn ló leégún
B’óṣó bá ń gbógun bí àjẹ́ ń gbógun bí alásàsí ń gbógun
Wà á fi Kurani bora Ishola
Ishola mi Raufu ọmọ Ìyálájé ọkọ Surajatu mi ọmọ Badiru ni Cotonou
Ìlù Benin republic mi, bí ẹ lé mi ní ìlú Nàìjíríà bí ẹ bá bínú
Ṣé ẹ ẹ̀ lè ṣe é?
Agbára ń bẹ lọ́wọ́ Àyìndé o
Walahi mo f’Ọlọ́hun búra
Ishola adé ẹni ẹni lẹni ẹni
Ọmọ ẹni ò ṣèdí bẹ̀bẹ̀rẹ̀, ká fìlẹ̀kẹ̀ sídìí ọmọ elòmíì
Ìṣọ̀lá mi ah, etí inú, etí inú
Gbogbo yín ẹ kú àdúrótì Aládé mi àbúgà Ọlátúnjí
Ah
Àbúgà Àlàdé náà
Òun náà ọmọ Benin Republic ni, ó kọ́lé sí Cotonou
Àlàdé mi Àbúgà Ọlátúnjí, Bàbá kú bàbá kù
B’álàdé bá kú àwa á rí Bíọ́lá Àbúgà ó dílé mú
Ọmọ Kura Muinu ní Cotonou
Owó ìlú wa ńlá ńlá ló ń ná
Làbàlàbà owó ìlú wa
Fẹ́mi, ìwọ kúkú ti dé Benin Republic rí
Owó ìlú wa, owó ńlá ló ń ná
Owó tí a fi ń sanwó ilé ìwé
Ìgbà tó wà ní Cotonou
Tí Fẹ́mi bá rírú owó yìí, owó ńlá ló rí
Ẹrù ńlá,
Etí inú, yí n bá ń ṣe Wàásí lọ́wọ́
Èyí yín ni kí ẹ yá mi
Òun ló ń mú Fújì mi yàtọ̀, Àyìndé Wasiu mi
Ẹ ò lè fi Fújì mi kí ẹ fi wé Fújì kankan
Ọlọ́tọ̀ tó ní tòun ọ̀tọ̀, arábámbí
Láti ìgbà àyé alálùmọ́lẹ̀ Àyìndé adé
Mo mọ àwọn tí a jọ re’lé ìwé
Mo mọ àwọn tó dé ilé ìwé lẹ́yìn mi Àyìndé mọ́gbọ́láhàn arábámbí
Yé ké ọmọ o (ọmọ yé ké)
Ṣé’mi ni bàbá ẹ (èmi ló ń bọ́ bukata lórí Mother ẹ o)
Èmi ló ń gbọ́ bukata lórí mother ẹ o
Ẹ má gbèrò mi one time
Ẹ gbè é Zigzag
Èmi ló ń gbọ́ bùkátà lórí mother ẹ o
Èmi Àyìndé lẹni ẹ bú
T’Ọba Olókè mi ò bú o
Èmi Àyìndé lẹni ẹ bùkù, tí Ọlọ́run Ọba ń bù kún
Ẹni ẹ pète pèrò pé ká fọwọ́ ẹ̀ dé’lẹ̀ pipele ló ń pele láyé ń bí
Orí mi ò ní ríbi nílé ayé ń bí
Alhaji Wasiu Ọba orin l’Àyìndé o
Ọlọ́hun Ọba atẹ̀léni má yà ni ẹ́
O mọ bí o ti ṣe ń ṣe o lọ́wọ́ ẹrú ẹ̀ tó dá
Ó máa bá mi ṣọ́ ẹ o Wasiu mi Àyìndé
Arábámbí, Ọmọ́gbọ́láhàn mi Àyìndé o
O ò ní rí’hun tó jù ẹ lọ, bó w’ọlá Muhammad o
Ṣùgbọ́n torí èmi kọ́ o, nítorí Muhammadu o
Muinu ọmọ Kura ní Benin Republic nílùú Cotonou wàá jayé pẹ́
Tí o bá ti délé bá mi tọ́jú arisco, ariscopa
Èèyàn ti lawali, lawali nílùú Cotonou Muinu
Awo Olúayé onífújì, títí dé New York City Arábámbí