wà l’wà (Live)-文本歌词

wà l’wà (Live)-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

Ìwà lẹwà ọmọ ènìyàn (Ò bá dákun tọ́jú ìwà ẹ) Ìwà ọmọ ní ń m’ọ́mọ ṣ’òkígbẹ́ Baàmi Àkànní Rasaki mi o Àwọn èèyàn pàtàkì pàtàkì Gbogbo wọn ń ba Ọlọ́hun Ọba dúpẹ́ Wọ́n ń dúpẹ́ fún Ọlọ́hun Ọba Lórí ìṣẹ̀míi yín fún ọjọ́ọ̀bí eléyìí o Lára àwọn ni His Excellency General Ike Nwanchuku Wọ́n ní kí n ba yín dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́hun sati Ọba Wọ́n ń ba yín dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́hun Ọba Wọ́n ní Ọlọ́hun Ọba ló lè ṣé o èèyàn kọ́ Ìyẹn ni a ṣe ń f’ògo hàn sí Ọlọ́hun Oore tó ṣe fún ẹ lórí i yín lójoojúmọ́ A wá ń bẹ̀ ẹ́ o Ọlọ́hun Sati mi o Lórí Rasaki mi Àkànní Ẹyin lójú l’Àkànní adé jẹ́ fún gbogbo wa Là ń rá bàbà síwájú Ọlọ́hun wí pé kó da yín sí Ká a ri yín pẹ́ Àkànní Rasaki mi o ìwà ni Kábíèsí Ọba Adéwálé Adédàpọ̀ Ọba Tẹ́júọshọ́ Wọ́n ní kí n ki yín Wọ́n ní ẹ kú oríire Àwa tá a péjú eléyìí o, a tún jọ máa ṣe tóńbọ̀ ni Àkànní Rasaki mi Gbogbo àwọn olorì ayaba t’òkè ọnà wọ́n ní kí n ki yín Gbogbo Ọba ládé ládé Wọ́n ní n ki yín Wọ́n ní ẹ ṣe ọdún eléyìí o Ẹ̀ ẹ́ ṣ’ẹ̀míì Àyìndé Olúgbọ́n asáakin Àrè pagidìda sọ’gi di ọmọ ènìyàn Ọkọ ọmọba Adéṣọlá, Ṣọlá baby ọmọ bàbá Làgbámú Ọmọ Ọba ni Ṣọlá Ìbá ṣe pé ọmọbìnrin ń jọba lórí orí ìtẹ́ o A à bá gbádé fún Ṣọlá Ṣùgbọ́n bàbá tó bi lọ́mọ ó ṣì ń bẹ láyé Prince Samuel mi ọmọ Adédoyin Bàbá gangan fún’ra ẹ̀ Ìwà ọmọ ní n m’ọ́mọ ṣe òkígbẹ́ Ẹ tọ́jú ẹ̀ dada Ìwà lolúwa ń wò, ò bá dákun tọ́jú ẹ̀ dada Ìwà yìí ló ṣòwo Ló ṣe ohun gbogbo ní mèremère ò bá dákun tọ́jú ẹ̀ dada Ìwà loníwà mí wò bí ò bá ti ṣí anybody mọ́ Baàmi Àkànní, ìwà ṣe pàtàkì pàtàkì Àdélébáre Àdélébáre Àdélébáre Àdélébáre Àdélébáre Àrìnàkore Àkòyà ibi ìwà ẹni ni Àkànní oníwà ló nìwà o Ìwà ọmọ ní n m’ọ́mọ ṣe òkígbẹ́ Ò bá dákun tọ́jú ẹ̀ dadada Ìwà lẹwà ọmọ ènìyàn (ò bá dákun tọ́jú ìwà ẹ ) Ìwà lẹwà ọmọ ènìyàn (ò bá dákun tọ́jú ìwà ẹ ) Arábámbí ń jayé ọba o (Ṣàngó ì í jobì àf’orógbó) Arábámbí ń jayé ọba o (Ṣàngó ì í jobì àf’orógbó) Baàmi Àkànní, àrábámbí ń jayé ọba o (Ṣàngó ì í jobì àf’orógbó) Àkànní adé ń jayé Ọba (Ṣàngó ì í jobì àf’orógbó) Ẹ kí Olúkòṣo àyánrán iná (Ṣàngó ì í jobì àf’orógbó) Ẹ bá mi kí Olúkòso àyánrán iná (Ṣàngó ì í jobì àf’orógbó) Abirin pípọn f’ọmọ lójú ọkọ Ọya (Ṣàngó ì í jobì àf’orógbó) Awàláòjí Ọbakòso (Ṣàngó ì í jobì àf’orógbó) Omi Àjànàkú o má fiyọ̀ si (Ṣàngó ì í jobì àf’orógbó) Ẹ kooo Ẹ kooo Ẹ kooo Ẹ kooo Ẹ k’ólúkòso àyánrán iná (Ṣàngó ì í jobì àf’orógbó) Ọmọ onílé ajé là ń kí (Ààrẹ gangan Àkànní) Ọmọ onílé ajé là ń kí (Ààrẹ gangan Àkànní) Ọ̀rẹ́ Sàámú Adédoyin Sàámú Adédoyin Sàámú Adédoyin Kiní tó o pé ó bùn mi ńkọ́? (À bó ò ní bùn mí mọ́) Ọ́ ṣàánú (ọ́ bùn mi) Ọ́ ṣàánú (ọ́ bùn mi) Ọ́ ṣàánú (ọ́ bùn mi) Ọ́ ṣàánú (ọ́ bùn mi) Ọ́ ṣàánú (ọ́ bùn mi) Ọ ṣá mọ̀ pé ǹ lẹ́nìkan Ọ́ ṣàánú (ọ́ bùnmi) Ọ́ ṣàánú (ọ́ bùnmi) Ọ́ ṣàánú (ọ́ bùnmi) Kiní tó o pé ó bùn mi ńkọ́? (À bó ò ní bùn mí mọ́) Ọ́ ṣàánú (ọ́ bùn mi) Ọ́ ṣàánú (ọ́ bùn mi) Ọ́ ṣàánú (ọ́ bùn mi) Ọ ṣá mọ̀ pé ǹ lẹ́nìkan Onílé ajé là ń kí (Ààrẹ gangan Àkànní) Ọ̀rẹ́ sàámú Adédoyin Ọ̀rẹ́ sàámú Adédoyin Ọ̀rẹ́ sàámú Adédoyin Ọ̀rẹ́ sàámú Adédoyin Àmín o ọmọ ni ó jogún rẹ (Àmín o) Àkànní ọmọ ni ó jogún ẹ (Àmín o) Mo damọ̀ ni mo ṣe ń kọ Àyìndé Onílé ajé Ọkọ́ya Àkànní Rasaki Happy 85 Birthday márùnlélógúnmẹ́rin Àkànní adé Baàmi nínú ọlá ńlá Ọkọ Adija kubura Oritókẹ́ Àkànní ọkọ Noimotu mi Àna Ọláńrewájú mi ọmọ Tẹ́júọshó Senate máa wolẹ̀ Láńrewájú Àkànní Ọkọ́ya onílé ajé Eleganza Ọkọ́ya Àkànní Eleganza Ọkọ́ya Àkànní Bí n bá f’ojú kan Ọkọ́ya Àkànní Rasaki Wọn kì í dá’ni lé òfo Bíọ́dún dé Kẹ r’ọ̀dọ̀ Rasaki o ọmọ onílé ajé mi Àkànní Ọkọ́ya tó ń jẹ́ Eleganza Mo mọ̀’wọ̀n ara mi (Mo yáa b’ọ́kọ́ya lọ) Àkànní Onílé ajé (Mo mọ̀’wọ̀n ara mi) (Mo yáa b’ọ́kọ́ya lọ) (Ayé ni n ó jẹ mi ò ní jìyà) (Mo mọ̀’wọ̀n ara mi) (Mo yáa b’ọ́kọ́ya lọ) Àkànní onílé ajé (Mo mọ̀’wọ̀n ara mi) (Mo yáa b’ọ́kọ́ya lọ) Ọmọ onílé ajé (Mo mọ̀’wọ̀n ara mi) (Mo yáa b’ọ́kọ́ya lọ) (Ayé ni n ó jẹ mi ò ní jìyà) (Mo mọ̀’wọ̀n ara mi) (Ayé ni n ó jẹ mi ò ní jìyà) (Mo mọ̀’wọ̀n ara mi) Ọkọ ti ìdùnnú Ọkọ́ya Noimotu (Mo mọ̀’wọ̀n ara mi) (Mo yáa b’ọ́kọ́ya lọ) Noimo òun ni Baby Ọkọ́ya tì ẹ́ yàtọ̀ (Mo mọ̀’wọ̀n ara mi) (Mo yáa b’ọ́kọ́ya lọ) Áńgẹ́lì Àkànní Ọkọ́ya Noimotu (Mo mọ̀’wọ̀n ara mi) (Mo yáa b’ọ́kọ́ya lọ) Àkànní Rasaki mi A dúpẹ́ fún Ọlọ́hun Ọba B’Ọ́lọ́hun Ọba ṣe ṣe Ọlá Aliko máa wolẹ̀ ọmọ Dangote Séríkí Me’rice Séríkí Me’Sugar Séríkí Me’diesel Séríkí Me’oil Ali máa wolẹ̀ Aliko máa wolẹ̀ o máa rọra O mà kú àdúrótì Àkànní Rasaki mi Onílé ajé baàmi Rasaki mi Àkànní Nínú àlàáfíà ká ri yín pẹ́ Nínú ẹ̀mí gígùn ọlá ńlá Governor Babájídé ọmọ Sanwoolú Ó ní kí n ki yín lorúkọ Aṣíwájú Àkànbí Olódó idẹ Wọ́n ní kí n ki yín Àkànní nínú àlàáfíà pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn Ẹ ẹ́ ṣe ọ̀pọ̀ ọdún láyé Ọlọ́hun Ọba o atẹ̀lénimáyà ni ẹ́ O mọ b’ó ti ṣe ń ṣe sọ́wọ́ ẹrú ẹ̀ tó dá Òun ló ń bá mi ṣọ ẹ́ Rasaki mi Àkànní Àkànní onílé ajé Eleganza mi Àkànní Ọkọ Adija Kubura mi Àna ti Sule Shadow mi Rasaki Àkànní Ọkọ Noimotu mi òyìnbó Ọkọ́ya Noimotu mi òyìnbó Àkànní o ò ní rí’hun tó jù yín lọ Bó wọlá Muhammadu o Ṣùgbọ́n nítorí èmi kọ́ o (nítorí Muhammadu o)