Kògbagídí (Live)-文本歌词

Kògbagídí (Live)-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

General

Sammy Larry

Sammy Larry gangan

Kògbagídí, ohun Ọlọ́hun Ọba ó ṣe fún wa Kògbagídí

Oṣé!

Gbogbo yín ẹ kú ọdún

Ijó ọdún là ń jó, Kògbagídí

Ẹrù t’Ọ́lọ́hun Ọba ti tò fún ẹ kò ní dànù mọ́ ẹ lọ́wọ́

Ayé òní t’ẹ́rù ẹ palẹ̀

Kògbagídí, má a ṣe bo ṣe ń ṣe lọ má mà yíwà ẹ padà o

Ọlọ́hun l’Ọba ẹlẹ́san Kògbagídí

Ọ̀nà omi ń bá wọnú àgbọn ayé wa wa wa wọn ò ri

Kògbagídí, o ò dẹ̀ ní dọlárẹ̀yìn Amina

Lámidé láti Manchester

Lami (Lami)

O ṣé! Sammy Larry dà?

General, mo kí ẹ General Ọ̀túnba Cash

Obeki láti Dubai, Ọlámidé Baron láti Manchester

O kú Ìtọ́jú mi nígbà gbogbo Ọlámidé àdúrà ẹ á gbà

Obeki, o ò dẹ̀ ní dọlárẹ̀yìn láti Dubai

Aláṣẹ Shun Autos láti Atlanta

General ní n kí ẹ

Small, ọmọ alálùbáríkà ọmọ mi ni

Small láti London gbogbo London ńkọ́

Àánú Ọlọ́hun Ọba kò ní fi ẹ́ sílẹ̀ títí láíláí

Àdúrà ẹ á máa gbà lójoojúmọ́

Deja Vu, Atóyègbé (Atóyègbé)

Ọ̀túnba Cash to bá délé ko bá mi kí Abu

Abu Abel kẹ ma bá mi ki

Ọ̀túnba Cash Abu Abel ko ma bámi ki

Ọ̀túnba Cash òpó iná Istanbul èèyàn General General ọmọ Atóyegbé

To bá délé ko bá mi kí Abu

Abu Dodo, Abel Abu Abel ko bá mi ki

Abu Abel mi (Abu Abel mi)

Tímọ́tímọ́ Shun Autos Obeki láti Dubai

Cashy Ọ̀túnba Cash

Cash Obeki ló ní n kí ẹ o

Sammy Larry bí’wọ bá jayé títí ko bá mi kí Jamiu

Ó wà nílùú Mecca mi á bá’re wá sílé

Sammy Larry Irọ́ lẹlẹ́gàn ń pa ( wọn ò lè jẹ)

Èké lẹlẹ́gàn ń ṣe (wọn ò lè jẹ)

Obeki Ọ̀túnba Cash

General Irọ́ lẹlẹ́gàn ń pa ( wọn ò lè jẹ)

Èké lẹlẹ́gàn ń ṣe (wọn ò lè jẹ)

Odò ti gbé oníyẹ̀yẹ́ lọ (kò wa tán)

Ẹní bá wù kó jẹ Soda kó ma b’ómi lọ

Tẹ bá sọ títí bí wọn ò bá gbà o

(Kò burú àgbò méjì wọn ò gbọ́dọ̀ momi ní koto)

Sammy Larry

Tẹ bá sọ títí bí wọn ò bá gbà o

(Kò burú àgbò méjì wọn ò gbọ́dọ̀ momi ní koto)

Ẹ tọ́jú Abu Abel mi (Abu Abel mi)

Ọ̀túnba Cash ko tọ́jú ẹ fún mi (Abu Abel mi)

Èkó ni wọ́n ń pe’bí (Èkó ni wọ́n ń pebí)

Ìhàhín na Lagos (Èkó ni wọ́n ń pebí)

Ìhàhín na Lagos (Èkó ni wọ́n ń pebí)

Mosh Kílóṣẹlẹ̀?

Ìhàhín na Lagos (Èkó ni wọ́n ń pebí)

Ìhàhín na Lagos (Èkó ni wọ́n ń pebí)

Ìhàhín na Lagos (Èkó ni wọ́n ń pebí)

Ìhàhín na Lagos (Èkó ni wọ́n ń pebí)

Ọ̀túnba Cash Ìhàhín na Lagos (Èkó ni wọ́n ń pebí)

O jù wọ́n lọ tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ̀ (ṣèbí ojú ni wọ́n ń yá)

Ọ̀túnba Cash sọ fún Abu

O jù wọ́n lọ tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ̀ (ṣèbí ojú ni wọ́n ń yá)

Obeki o jù wọ́n lọ tẹ́lẹ̀ tẹ́lẹ̀ (ṣèbí ojú ni wọ́n ń yá)

Abu o (Abu o)

Ọ̀túnba Cash tọ́jù Abu o (tọ́jú Abu o)

Sammy Larry bẹ́ẹ̀ náà ni (bẹ́ẹ̀ náà ni)

Ọlọ́hun ló ṣe àdéhùn yìí o (bẹ́ẹ̀ náà ni)

Pé òun ò ní fi ẹ́ sílẹ̀ fún ìyà jẹ (bẹ́ẹ̀ náà ni)

Ó dẹ̀ ṣì mú ìlérí ẹ ṣẹ (bẹ́ẹ̀ náà ni)

Sammy Larry bẹ́ẹ̀ náà ni o (bẹ́ẹ̀ náà ni)

Cash bẹ́ẹ̀ náà ni (bẹ́ẹ̀ náà ni)

General Atóyègbé (bẹ́ẹ̀ náà ni)

Shun motors òyìnbó onímọ́tò

Shun bẹ́ẹ̀ náà ni (bẹ́ẹ̀ náà ni)

Atlanta Georgia èèyàn ti Diesel olóyè

Bẹ́ẹ̀ náà ni Sammy Larry (bẹ́ẹ̀ náà ni)

Sammy Larry, striker gbogbo ìdí òro

Bẹ́ẹ̀ náà ni (bẹ́ẹ̀ náà ni)

Ọlọ́hun ló ṣe àdéhùn yìí o bẹ́ẹ̀ náà ni (bẹ́ẹ̀ náà ni)

General Ọlọ́hun ló ṣe àdéhùn yìí o bẹ́ẹ̀ náà ni (bẹ́ẹ̀ náà ni)

Òpùrọ́ ń gbin ilá (oníwà yó gbìn’gbàdo)

General Atóyègbé èèyàn Deja Vu Shun

Ọ̀túnba Cash wọ́n jíṣẹ́ ẹ fún mi o ṣeun mi

Ojú ò kí ń tère ojú ò ní tì ẹ́ wa máa rówó pè ránsẹ́

Onílé yami yami inú pinnoch estate

Pinnoch estate ṣá lọmọ wà onílé yami yami

Sammy Larry òpùrọ́ ń gbin ilá (oníwà yó gbìn’gbàdo)

Sammy Larry òpùrọ́ ń gbin ilá (oníwà yó gbìn’gbàdo)

(Sínú oko t’álábòsí mà dá o)

Sínú oko t’álábòsí mà dá o)

Àti ẹ̀kì àti ajá wọn o (ìyẹn rọ́ Kòkò o)

Okay ẹ jẹ́ á kàá síwájú kí là ń ṣe tánàdí ara wa fún ná?

(Kí là ń ṣe elénìní ara wa fún ná)

Shun, Ọ̀túnba Cash kí là ń ṣe tánàdí ara wa fún ná?

(Kí là ń ṣe elénìní ara wa fún ná)

Ọ̀túnba Cash bàbá ẹdúnjọbí ní Maryland

Sammy Larry sọ fun wọn kí là ń ṣe tánàdí ara wa fún ná?

(Kí là ń ṣe elénìní ara wa fún ná)

Bàbá Ẹdúnjọbí bàbá ẹdúnjọbí bàbá ẹdúnjọbí bàbá ẹdúnjọbí

Kí là ń ṣe tánàdí ara wa fún ná?

(Kí là ń ṣe elénìní ara wa fún ná)

B’órin ta kókó lágbolé Fújì

(Ìrùkẹ̀rẹ̀ ifá ni mo máa rán o kó lọ bá mi wo ọ̀rọ̀ yẹn)

Shun bó ta kókó bó d’ẹlẹ́ẹ̀kejì

B’órin ta kókó lágbolé Fújì

(Ìrùkẹ̀rẹ̀ ifá ni mo máa rán o kó lọ bá mi wo ọ̀rọ̀ yẹn)

Bó tún ta kókó bó d’ẹlẹ́ẹ̀kẹta

(Ìrùkẹ̀rẹ̀ ifá ni mo máa rán o kó lọ bá mi wo ọ̀rọ̀ yẹn)

Ó pọ̀ fún ẹ púpọ̀ (ó pọ̀ fun)

Shun ó pọ̀ fún ẹ púpọ̀ (ó pọ̀ fun)

Ó pọ̀ fún ẹ púpọ̀ (ó pọ̀ fun)

Ọ̀túnba mo ló pọ̀ fún ẹ púpọ̀ (ó pọ̀ fun)

Obeki gbogbo Dubai Deja Vu dà?

Ó pọ̀ fún ẹ púpọ̀ (ó pọ̀ fun)

Ohun téèyàn fi ń ṣe ilé ayé l’owó

Shun,gbogbo yín pátá pátá Ọlọ́hun á gbe le yín lọ́wọ́

Ẹ̀ ẹ́ r’ówó ṣayé

General Ẹ̀ ẹ́ ríhun’re ṣayé nínú àlàáfíà

Shun Ọ̀túnba Cash Money ẹ̀ ẹ́ rí gbogbo nǹkan

Ẹ̀ ẹ́ ri fi ṣe ilé ayé

Sammy Larry, Ẹ̀ ẹ́ r’ówó fi ṣayé

Ìkan ò ní ṣẹrú ara wọn nínú gbogbo yín

Àdúà á máa gbà gbogbo yín ni mo kí