Láídé Quary (Live)-文本歌词

Láídé Quary (Live)-文本歌词

K1 De Ultimate
发行日期:

Alápá yẹbẹ yẹbẹ níbo lẹ̀ ń lọ o

(Ajùdí yaba yaba níbo l’ẹmí rè)

Kò sẹ́ni tó le nà mí lọ́rẹ́ (lójú tani)

(Òyìnbó tó ń ṣa paper o)

Láídé bẹ́ẹ̀ náà ni (bẹ́ẹ̀ náà ni)

Láídé, gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ tí wọ́n ń sọ

Wọ́n á rí yárò ṣèbí ó ti gbọ́

Fi gbígbọ́ ṣe aláìgbọ́, (gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ tí wọ́n ń sọ)

(Maria lo ṣá ti gbọ́)

Ọmọ Abeebah mà ni ọkọ sweety Ṣọlá

(Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹ tí wọ́n ń sọ Maria lo ṣá ti gbọ́)

Kúrò ńbẹ̀!

Mo ní gbogbo ìgbà tí o bá rán owó ńṣẹ́

Owó ẹ á máa padà wá

Àsọ̀kalẹ̀ àǹfààní, gbogbo owó tó o rán níṣẹ́

Yí ó di dọ́bùrù dọ́rùbù

(Arabic recitation)

Bó o bá rán’wó ní’ṣẹ́

Á máa padà wá

Èyí tó lọ s’ókè

Bí pẹ́pẹ́yẹ bá gòkè lọ ire ló máa kó wálé

Àsọ̀kalẹ̀ àǹfààní

(Arabic recitation)

Bó ti wù kí wọ́n lé ẹ, (wọn ò le bá ẹ lójijì rárá ni)

(Má mikàn o)

Láídé bó ti wù kí wọ́n lé ẹ, (wọn ò le bá ẹ lójijì rárá ni má mikàn o)

Ọkọ Ṣọlá baby (má mikàn o)

Kò ṣe nǹkan ẹ̀ láàbọ̀ rí o, lódidi ló máa ń ṣe é

Láídé ọmọ fowóṣeré

(Kò ṣe nǹkan ẹ̀ láàbọ̀ rí o, lódidi ló máa ń ṣe é)

Olókuta, má mikàn Láídé

Olówó Quary méjì lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo

Kò ṣe nǹkan ẹ̀ láàbọ̀ rí o, lódidi ló máa ń ṣe é

Ọlọ́hun Ọba ló ń ṣè’yẹn o

(Kò ṣe nǹkan ẹ̀ láàbọ̀ rí o, lódidi ló máa ń ṣe é)

Ọkọ Ṣọlá (Ọkọ Ṣọlá)

Ọkọ Ṣọlá (Ọkọ Ṣọlá)

Ọkọ Ṣọlá o (Ọkọ Ṣọlá)

Láídé kò ṣe nǹkan ẹ̀ láàbọ̀ rí o, lódidi ló máa ń ṣe é

Bí Quary bá ju mẹ́fà lọ o

(Kò ṣe nǹkan ẹ̀ láàbọ̀ rí o, lódidi ló máa ń ṣe é)

(Arabic recitation)

To bá rán owó ẹ níṣẹ́

Á di double wálé

Bí ẹyẹlé bá gòkè lọ

Ire ló máa mú padà wá o

Àlàáfíà kó jẹ́ tì ẹ

Àsọ̀kalẹ̀ àǹfààní

(Arabic recitation)

Èèyàn tí a bá fẹ́, kó máa ṣe oríire ní dọ́bùrù dọ́bùrù

Kó máa ra ẹrù ẹ̀, kó máa sọ̀ ọ́

La máa ń ṣe irú àdúrà yẹn fún

(arabic recitation)

Ènìyàn tó r’ẹrù báyìí, t’a fẹ́ kó sọ̀ ọ́

Tí a ò fẹ́ káráyé fẹrù dààmú ẹ̀

Ayé òní ṣe ẹ́ ní ẹlẹ́rù lásán

Wàá máa rù ú, wàá ma sọ̀ ọ́ pẹ̀lú àṣẹ Ọlọ́hun ọba, Ọláídé

(Arabic recitation)

Ọkọ Ṣọlá

(Arabic recitation)

Ọmọ Fowóṣe (Ọmọ Fowóṣeré)

Ọmọ Fowóṣe (Ọmọ Fowóṣeré)

Mo ti pè é kó o tó dé’bí

Ó dẹ̀ ti náwó, mo pe Ọmọparíọlá

Mo pe Láídé ẹ̀gbọ́n ọmọge Saida

Ó dẹ̀ ti náwó kó o tó débí

À fi ṣe’ni kí o d’ówó náà padà fun ní double double

Àna ẹ náà, ó ti náwó kí o tó dé’bí

Láídé mi ọmọ Fowóṣeré ọkọ sweety Ṣọlá

Ṣọlá baby o (sweety kan baby)

Olorì láàfin (Ṣọlá Baby mi o)

Olorì láàfin (Ṣọlá Baby mi o)

Aya Fowóṣeré o (Ọmọ paríọlá mi o)

Aya Fowóṣeré (Ọmọ paríọlá mi o)

Gbogbo ẹ̀ ń dùn ó ń dán báyìí (Paríọlá mi o)

Kò ní kan lọ́lá Ọlọ́hun Ọba (Ọmọ Paríọlá mi o)

Mo ṣe Àmín àṣẹ (Paríọlá mi o)

Ṣọlá kò ní kan lórí tì ẹ (Paríọlá mi o)

Aya Ọláídé o

Aya Ọláídé o

Awo tèmi Àyìndé o (K1 De Ultimate)

Awo t’Àyìndé (K1 De Ultimate)

Alápá yẹbẹ yẹbẹ níbo lẹ̀ ń lọ o

(Ajùdí yaba yaba níbo l’ẹmí rè)

Kò sẹ́ni tó le nà mí lọ́rẹ́ (lójú tani)

(Òyìnbó tó ń ka paper o)

Láídé bẹ́ẹ̀ náà ló kúkú rí (bẹ́ẹ̀ náà ni)

Láídé bẹ́ẹ̀ náà ló kúkú rí (bẹ́ẹ̀ náà ni)

Bẹ́ẹ̀ náà ló kúkú rí (bẹ́ẹ̀ náà ni)

Ọlọ́mọge skimpy skimpy yìí (ìwọ là ń kí)